Aisan Lyrics & Tabs by Lagbaja

Aisan

guitar chords lyrics

Lagbaja

Album : Africano ...The Mother of Groove nigeria PlayStop

Ko gbodo mu mi ju e o
Ko gbodo mu e ju mi o
Bo ba sesi mukan jukan

Pagidari! awo se kini o
Awo fe fo niyen
Se wipe won sope
Abokoku ni e
Se wipe won sope
Mo ti ra, mo ra e niye
Se wipe won sope
Mo ti yi e lori
(scat)
Se wipe won sope
Ife npa e, bi oti
Se wipe won sope

Se wipe won sope
Ife npa e, bi oti
Se wipe won sope
Ife ti di e, o di e loju
Se wipe won sope
Bigbin fa ikarahun a tele
(scat)
Iwo figbe le fagbepo
Adimeru tiwon niyen
Falana gbo ti e
Tara eni la gbo
Se wipe won sope
Ife ti yi e lori
En! igba na wa nko
Amo, Oda naa, so fun mi o
Ka ma tan ra wa je
Ka soro sibi toro wa
Se won paro mo e ni
(Bridge: Ife yio Aisan ni...
Ife, ...Aisan)
Ife yi o, aisan ni
Se won paro mo e ni
Ife, (Oga oga oga) Aisan
Sabokoku ko ni e
Ife yi o, Aisan ni
Won o paro mo e ke
Ife, (Oga oga oga) Aisan
O wa mo un to je o daa
Ife yi o, aisan ni
Bo se nse e lo nse mi
Ife, (Oga oga oga) Aisan
Bo se nse mi lo nse e
Ife yi o, aisan ni
Ife yi npa emi mi oti
Ife, ...Aisan
O ti ko siwo lori
Ife yi o, aisan ni
O da emi ni gbese
Ife... aisan
O fo 'wo loju
Ife yi o, aisan ni
Eee... aisan ni o
aisan ni o, aisan ni o, aisan ni ooo
aisan ti o gb'oogun k'oluwa ma fi se wa
Amo, eyi ti se wa na, haa
Temi o gb'oogun afi wo (oga oga oga)
Ti e o gb'oogun af'emi (oga oga oga)
Itakun to s'ogba, to s'ogba, to s'ogba, to s'ogba
Lo s'agbe, lo s'elegede
B'ose n mu e lo n mu mi o
B'ose n mu mi lo n mu e
Ko yaa maa mu wa dogba baun ni o
Ko gbodo mu mi ju o ooo
Ko gbodo mu o ju mi oo
B'oba sesi mu kan ju kan
Pagidari awo se kini?
Pagidari awo se kini?
Pagidari awo se kini?
Pagidari, awo pai
awo fo
awo ya
awo tu mo won lori la i s'awa
(scat)
Ife yi o, aisan ni
Eyi ti se wa na
Ife... aisan
Temi o gb'oogun afi wo
Tire o gb'oogun af'emi
Ko gbodo mu mi ju e oo
Ko gbodo
Ko gbodo, gbodo mu e ju mi oo
Bo ba sesi mu kan ju...(scat)
Pagidari, awo se kini o?
Awo ya.
(end)

Like us on Facebook.....
-> Loading Time :0.0082 sec